Tope Alabi - Kokoro Igbala
| |

Tope Alabi – Kokoro Igbala

Contents

Download the Latest Song “Kokoro Igbala” By Tope Alabi

Tope Alabi - Kokoro Igbala
Kokoro Igbala Mp3 Download, Lyrics, Album, Video & Mp4

Talented Gospel Music Minister Tope Alabi Releases His New Single Titled “Kokoro Igbala”. The Song is Available on All Digital Music Platforms for Streaming & Download.

“Kokoro Igbala” Is a Song Released By the Popular Music Minister Intended to Bless Many Lives, Insured With Nice Sound and Instrumental.

Listen and get the Audio Mp3 below

Download Mp3

Please Drop a Comment About the Music Below

Watch Mp4 Video Here

“Kokoro Igbala Lyrics” by Tope Alabi

Mo fi ope fun olorun fun pipe to pe mi sinu agbo igbala yii
Ogo ni fun oruko re loke orun
Nko se aibikita si anfani nla yi rara o
Pe olorunn le gba enu mi yii soro nla bayi
Modupe lowo baba mii ninu oluwa
Prophet i.a ajanaku ati ijo christ revival victory chapel
Idile mii, awon obi mi ati awon omo egbe mi lapapo
Ilese iranse mi
Ati gbogbo awon to ko pa ire laye mi pata
E ma tesiwaju ninu olorun
Mo gbadura pe nigba ti a ba dagba ti a si kuu
Ajogun ijoba olorun lapapo
Amin
Ore mii nibo lon le leyin aye
Nje to ba mo be ko wi fun mii
Tori aye nlo ati fekufe aye
Ojo ori eniyan nlo diedie
Ilu kan to waa to juaye lo
Waa mumi debe ye olorun mii
Hmmm
Ibeere mii lowo gbogbo eniyan to n gbo mii bayi
Ohun nin wipe nibo gan ni an lo leyin aye
Bi a ba se tan ninu aye yii
Oni ibikan ti a o ree
Ibo gan la n lo leyin aye
Aro lo n gbo mii osan tabi iya le ta, ibeere mi lowo e ni yii
Akosile ninu bibeli fi yewa wipe jesu nii ona otito ati iye
Enikeni to ba gbagbo yo ni iye ayeraye
Nitori na, ninu ese la gbe loyun wa
Ninu ese la si gbe bi wa
Ese je ohun abinibi lati odo babnla wa
Ati iya wa , tii se adamu ati efa
Lati ipase won nii olorun ti fii iran omo eniyan gegun
Eh o ri pe taba bimo , to ba tii mo oro so
A o ni komo na ni iro to fi maa paro, idi niyi
Ti jesu fi wa saye lati rawapada
O gba kokoro lowo iku , o nii isa oku isegun re da
Lati le fun wa ni iye ayeraye ni
Leyin na , enikeni to ba ko lati gba
Ko de tun atunbi, ko le ni iye ayeraye
Nitori wi pe ba pe laye ba o pe o
Iku lopin ohun gbogbo
Ba lowo laye ba o de ni rara , iku lopin ohun gbogbo
Eniyan ronu orun isinmi
Iku lopin ohun gbogbo
Ehhhh
Kile maa dariwo la mii ke tantan
Koro maa dariwo la mii kigbo si
Ko mo eleran ma pada wa jegun
Eni to laso ko ma pada wo akisa
Eniyan ro oooo
Eniyan ro ko ma ba se olorun oba
Mo leniyan roo,eniyan ro kese ma ba jare re
Ero to mo pe aye yii a wa na oja
E sumo bii
Ki gbogbo eni to saye da waa ilo ko ya ma gbo
Eni to ra nkan ipanu loja to dun se ko nii rele mo nii
Won da bi eni to ti gbagbe orun abi e mo pe ile la bo isimi oko
E ma tori aye , ke gbagbe orun o
Mo mii ke tan tan
E yo tii duniyan to.. Keniyan padanu ijoba orun
Komo eleran ma ja san efo sowa da
Ese loro iku lere ese orun apadi lon gbe ni re
Looto nii
Iku lere ese, orun apadi lon gbe nii re
Ki wa nii a pe ni ese gangan na
Galatia ori karun ese kankandinlogun ka si sale o tii je ko ye wa
Ohun tii a pe nii ese
To ba je ole , elese ni o
Ono to wun ko gba ja ole ohun , a ni ese ni
Bi o ba je alagbere ba kan na , ono to wun ko ma se agbere elese ni o
Alabosi eniyen elese ni , onilara , onijamba, aborisa , alagidi,
Onigberaga, olote eniyan , opuro .. Elese noni
Ese ko loruko meji , ese noni yo ma je
Nje a wa le waa ninu gbogbo ese, tabi ka muu lokan kan eyi toba je ti wa
Ka nii ki ore ofe ko ma posi
Nitori na ti aban je ese bii e ni jeran , tan mu ese bi eni mumi
Tasi wiwiwi to ni o nii gbo
Iya kan be nile fun elese , nibiti awon elese aye yii nlo
Won o je iya ayeraye nibe
Ibe ni awon ayan tii n je eran ara awon ti imi n pada sibe
Tori pe iya ayeraye nii
Igbe oro ni won ke nibe , ekun ohun ipayin keke lowa nibe
Je ka wa so nipa ile olorun , ijoba olorun ni mo n so nipa e
Ile logo, ilu elewa, ibode wura , ile didan tawon mimo
Nibi ti a tii so eru wa kale
Ibe la tii nu omije waa nu
Awon angeli sa n ko mimo mimo mimo
Nitoripe won ri ewa ogo olorun
O ri , oloro ati lazaru won je ore ninu aye sugbon
Nigba ti lazaru koja si ijoba olorun , oloro lo si ijoba orun apadi
Waa wo bii oloro se n be won,
Oni e ba mii so fun lazaru , ore mi ni
Eni ko fii ika re to omi simi lenu , sugbon aye o si mo
Iru aye bayi ko ni simo lorun
Aye to fi gbo oro ti mo n so bayi ko ni si mo lorun
Yo kun awon eniyan mimo ninu elewa
Yo kuu awon elese ayerayeti won ko ti won o gbo
Yo ku won nii ijoba orun apandi ….
Ile mimo lo ye wa o
Ilu elewa nii o tii dara to
Sioni oooo, ilu aye
Jerusalem o , ilu ogo
Afi gba tii oju mi bari o , ye o ma gbagbe gbogbo iya ti moje
O tun gbo ni , jerusalem torun
Orin mi ilu mi, ile mi ti n ba kuu
Ekun ibukun mii
Ibi ayo , igba wo lemi o roju re
Olorun mii
Nigba wo lemi o roju re
Se iwo na le so be bayi
Gbogbo iya wo lo ba ma je lowo bayii
To mu o pada , to so pe o ni gba jesu
Iru aye wo lo n gbe lowo lowo bayi
Iru awon nkan wo lo n la koja gan
To so wipe jesu o to si e lasiko yii
Pe toba lowo tan o pada wa gba
Ola ma le peju fun o,
Iru kini nkan to se e gangan bai
Arun wo lo sodo siny aye re
Ti o fi o lorun le totori e sanwo re
Ton ko owo e fun babalawo
Kini nkan ton da o lamu
To bere sini wo egbe imule kakiri
Somo kan na tobi yi noni
To sope o wo inu egbe imule tori re
Se nitori owo to fe ni to ri pe won eniyan soro egan si o
Tori pe o je talika
Iyen na lo fe wo egbe imule si
O fii aye re fun satani ti o ni aanfani kankan rara
Boba faye re fun satani iya ni fi jeyan
Nitori pe afuni lokan fi gbedegba lowo eniyan nii satani
Bo baa fi aye e fun ko si ohun ti o fun o
Ofo ninu ofo , asan ninu asan noni yo pada fun o
Woo, iya to re ko le ma je lowo a nii ko gba jesu ko di lowo muu shishin
Nitoripe o ye ko gba
Ona kan niyen, enikan ta fifun wa niyen laye ati orun
Oni eyi ni ayanfe omo mi , eni ti inu mi dun si gidi
E maa gbo ti re
Bibeli tun fese re mule bakan na wipe
Ati fun wa nii oruko kan to ju gbogbo oruko lo wipe ni oruko jesu ki
Gbogbo ekun ko ma wole
Ma gbagbe o wipe aye yii a waa noja nibe ni orun ni ile gbogbo wa
E ma ma je ka gbagbe o
Pe ajo laye yii orun nile waa
Bo ni kaluku ti noja loja
Lakoko nlo , ile nsu o
Bi le ba ti suu dandan ni ka re le o
Ajo laye yii orun nilewa
Igba kan lo igba kan bo
Book ba rokun rosa a fori fe elebute
Bi odo gbogbo ba san titi, wan sho sinu okun
Won ba tin wa lan dari lo
Ba o pe laye ba o pe o
Iku lopin hun gbogbo, eniyan ro o
Ro o ro re
Beeni
Riro riro lan ro obe gbegiri
Baa ba ro yo san yo domi lasan nii
O san fun wa ka wa ninu jeska gba nii oluwa ati olugbala wa
Juu ka wa ninu owo ola ohun meremere alumoni aye yii
Lai ni jesu lo
Enikeni to ni awon nkan won yii ti jesu o fese mule ninu aye e
Eru ni , eru ni irun ohun tohun
Bi a ba si ka eru , inu eru a baje
A o ka e ni ojo kan , se si epo tabi alukama
Ehhhh
Jesu ti so fun wa , o ti fi irorun si aye wa
O ni e waa si odo mi gbogbo eyin ti e n sise ati ti a di eru wiwo si lori
O ni e mi yo fi isinmi fun okan yi
O gbo to so nii
A ko tu seru
A ko tuu seru
O tii wa loko igbekun waa
O so wa dalayo
Ninu iparun lo tii wa wa ri
O muu wa pada wa sagbo
Ati rii igbala ofe ninu jesu
Awa tii ye
Bo ba sale
Bo tun soru
Ojo tii jesu ba de oo
A o pade e lawo sumo , a o deni aiku lo odo re
O nii a o denii aiku
A o tun nii seru mo
Bibeli ni e tete maa wa ijoba olorun na ati ododo re
O nii eyi to ba kuu a o fifun wa
Hmmm
Sugbon ni ode woyi
E wo gangan la kankan wa na
Shebi e yi to kuu leyin re lasaju waa
Ati fi ijoba olorun sile , a waa n sare eleyi to wa leyin
A sa mi asa pa oju de
A sa imi wole esu lai jade mo tori pe olele to maa wonu eko ko tun jade mo loro esu
A sa imi gbagbe orun
A sa n sa
A nsa so gbogbo hun tani nu
Elomi nsa tie o n samo nu
O nsa saya nu
Won sa won soko nu
Sugbonn so ye ka ma sa ere wleyi to wa leyin
Abi ere eleyi to wa niwaju to ni ka koko wa yen na
Ohun lo ye ka sa
Aye n fawa mora pelu gbogbo ohun tiwon ni sugbon aye n jawa kulo nigbeyin noni
Hmmmmm
Lasan laye yii
Fi ogo ati afe re han mi
O fa mi mora , kile je omo aye
Ohun won yi o ko ni bori mii
Ki mi ki ma foya
Iwo na pete pero ko mberu
Awa n wa oreofe ebun kan soso nii
Gbogboo eyi to ku dabi ojiji to kojaa
Eje ka wa iye ogo torun tooto
Tori orun lo jaju oo
Sowun lo jaju ooo
Magbo
Bii a ba padanu jesu a padanu ohun gbogbo
Irorun isinmi igbala ti o nipekun
Alafia to ye ka wa ni lati wo orun rere
Ani nile ologo ke mi ma padanuu
Ko ye ka padanu ile ologo ka ri ra lorun lo ja juu
Ko ye ka faye yii sa ri mo
Gbogbo ohun ta ni ninu aye yi
Bi a ba ni jesu ofo lo jasi
Ka rira lorun lo jaju
Ko ye ka faye yii sarimo
Ka rira lorun lo ja ju
Ko ye ka faye yii sarimo
Hmm
Ko ma ye ka faye yi sarimo
Ki sorin lasan logbo yen o
Iwo ole so wani faye yi sarimo bayi
Ati ibi kobo kobo five five naira sisi sisi lo ma ti bere
To fi wa di hun to da mo e lowo yi
So wa n faye yiii sarimo toba jawo
Alagbere mo d’odo re o
Nigba ti were wan ii titi ti owo aso
Nitoripe opolo e tii daru ko mo kan ti o n se mo
Ti iwo eyan tori re o daru tori re o yi
O wole ibi ti won ti n taso, toni wowo lo ra
O tun bo baluwe o tun we bakana o wa n rin lo ni titi gbogbo ara re la n wo
O yato si were
Ka wa ma pe iwo ati were ni nkan kan na ni
Awon alagbere kan wa, highclass niti won
Won ki wo aso to si ara le
Koda awon elomi a tun bori ninu won
Sugbon ponbele ogidi agbere lo n be lowo won
Bii won ba wo ijo olorun iranse olorun to wa nibe won fe gbe subu nii
So wani faye yi sarimo bayi
Alabosi eniyan ti n tenu bole rojo elejo kaakiri lai da
Soni faye yi sarimo
Iwo oni lara eniyan to je wipe to bar ii ohun to da bayi
A nii kini
Awon da …. So ni faye yii sarimo bayi
Oni jamba eniyan ti n pada awon eniyan lese ogbeji abi ti n pe eniyan pa loru
Abi oruko omo lomo pa
Ehhhhhh, so ni faye yii sarimo
Aborisa, elegbin ni o , onidoti ni e
Gbogbo ohun ta gbe fun o pe ko gbe sinu cumboard abi abe ile e to n tapo si lori
To n buyo si , to n ko egbin mo ra
O rip e obun niyen , ohun irira ni loju olorun
Show a ni faye yi sharimo bayi to ba lo jawo bayii
Iwo alagidi eniyan ta so fun e titi to ni o ni gbo , to ni tinu e nani o se
O da gbogbo e ru noni sugbon a ri koko , so wan i faye yi sarimo bayi
Oni gberaga , emi ni mo to bayi, emi ni mo po bayi
Ko si eni to to mi nile yii… sho ni faye yii sarimo bayi
Olote eniyan awon ti n da ile ijosin ru nuu won po ni ile ijosin
Wan si da gbogbo egbe ru, la gbogbo e mo le
Sho ni faye yii sharimo
Opuro eniyan ko… lo jawo ko ma ba faye yi shaarimo
Ehh mon so
Oniwakiwa ronu ko lo jawo
Alagbere oniwokuwo e ya sose
Ole janduku eku ireti ojo idajo
Ka borisa ko pa ohun ti o soro tii
Ko si olorun
E ye bo satani lowo ke tun fe nu ko jesu
Seke sajo ko si eni ti o gbin alubosa e gbo to maa fi kala
Iyen dewo
Bi a ba gbo tomode gegi nigbo
Agba lo le mo ibi to mi a wo si
Tomode ba ririn ajo loju agba
O le ma gbagba mo nile to ba de eee
Irin ajo eda laye olorun lo mo
Opin irin ajo ta ka fii sadura
Opin irin ajo temi tire ninu aye
Oba je ko sanwa o ka jagunmolu
Boda boys mo maa d’odo eyin na
Eyin to je pe teba ra shirt fun yin e ni de button bo ti le wun ko ri
Eni de to w obo ti wun ko kere mo
E waa shi gbogbo aya le
E ma gbo wassup gee kilon happen now
Eyin guys nibo la n chill si
Lsti secondsry school lo ma tii bere titi te fi wo university
Te fii wo polytechnictabi awon technical school
Le baa tun lo kasa nibe te ba de ile iwe
Elo mi a rin a dabi pe egbe e ti wo danu nitori ako yi noni
Elo mi a rin a dabi eni to suke
Elomi a darungbo si dabi tobuko
Won ti wa domo komo won ti ya gasha
Lawon omo to bi nibi niran omo
Haa
Elomi ti lo join cult ti ba pada dele ti n ba baba e soro
E ma wo pe ye omo re
Ago owo re lekenka, beliti gan o se ko
Eti ri oju owun gan fun ra e si
Olorin ko lo korin nigba kan
Oko ero laye awa eda
Bi adari oko lori wari
Eleda eniyan lo je di owner
Igbesi aye wa gegebi oko to n rajo
Nje e tii ri arinri ajo to so pe o wun o tun rele mo
Boko ba rokun rosa ebute ni o ti lo re jabo
Ono abuja ta o gbabo, atiko ti ko wa wa yo rele
Iru oko ta o wo la o mo
Ile aye yii a wa noja nii
Ajoji la je laye
Ajoji laje laye
Bo ti wun kaye yi ladun to
A oo pada lojo kan
Ile aye yii a wa noja nii
Oja re to wa na noni yii , pe ko jabale omolomo ko puro fun ko fun loyun
To ba ti mu de leyin ko so pe o ti ri ra
Ojo re to wan a ni ko ko ma gbe are re le fokunrin to ba ti waya koo degun si e lori
Ko ma roko fe
Oja re to wa na ti e ko so fun eniti o n lo phone e lowo pe to ba ti lo fone owo e tan ko gbe le mi lowo
Hmmmmmm
Oja re na to wa na niyen
Oja re to wan a ohun nani ko di digbolugi si igboro, ko wa di omo ita kale ko di oraisa
Ishan meji tii cut itan kan ma ni
Omo okunrin kan lo jade ile iwe giga ni o ba ri ise
O wa ise tititi ko maa ri ise
O waa ranti ore re l’oshodi ton se driver
Ohun o kuku lo ba ma se conductor titi ti owun na yo fi ri ise
Ore re yi wa pe kale , pe o need lesson o
Gbogbo eni ti yo ba sise pelu awa bayi , wahala ma sele kakiri gbogbo awon terminal
Taba de gbogbo be, ti onikaluku ba ti n yo obe , talake ti n yo ake
Iwo na o bere mu to ba je igo lowo re ba o jon mo ogiri tabi ibikan
Sa gun ara e ni igo na toba ti koko denu legbe ara re na
Wa wa se se maa denu legbe awon eniyan to ripe
Eni ori yo , o dile ni o
Omo okunrin yii nipe ohun ti gbo… ija ba sele loshodi
Nijo ta n wi yi, ojo na tip e die seyin
Lomo yii ba kigo mole nigba to rip e ija yii bere
O ba gba igo mole lo ba gun ara re
Ori ishan meji to n be ni atelewo ibe lo ti gba igo yi mo ara re
Haaa ishan meji ba gbenu soke bayi lo n ta eje shoro shoro
Loba bere sini pariwo ishan meji ti cut bayi ,yes, ija sese bere ni
Ishan meji ti cut , katowi katofo laarin iseju meji , omo yii
Ti fegbe lele o tii daku … idaku nikan leri
Koto gbede ile iwosan omo yi ti gbemi mi
Haa omo ti iya tii jiya jiya lori , to tii lagun lagun tori titi e
Won sope nijo kana won o joko awon o jere omo awon
Haa omo yi ma fo shan le o ma ku
Ishan meji ti cut , ehh se awa ri ere nbe bayi
Nje ere wa ninu agidi, nje ere wa ninu janduku , so rere gidi nbe bai
Nje ti eyan ba ti e rere ninu aye se eyan le rere lorun
Bo ba ti e rere janduku eh ninu aye sho ri lorun
O nii lati yi pada
Ranti omo eni ti iwo nse o
Aye o lo bii opa ibon
Atori laye, o nlo si wa seyin o
Pasan laye o… o nlo si wa seyin
Ranti eleda re nigba ewe re, nigba tii ojo ibi ko tii de
Omo mi gbo telegan ba tan e ko ma se gba
Iwa rere sha sho wun leso eniyan
Fe ti si ohun awon obi re ma se kegbe kegbe o
Ogbon kigbe lode on fohun re nii gboro
Ogbon kiigbe lode o on fohun re tantantan
Wipe ki eni to ba leti kogbo ohun temi nso fun ijo
Iwo to so pe o gba jesu ni oluwa ati olugbala re
A gbooo, inu wa dun pe o so be , sugbon
Ni gba to shi beer parlor nko iru igbala wo gan lo fi han awon eniyan
To da ile ise beer parlor sile to tun pe ni ogo oluwa beer parlor
Iwo to pen i iyanu jesu beer parlor , iwo to pen i jesu seun beer parlor
Se ogo olorun fara han nibi to wa yen , ogo olorun a ma fara hank i eniyan muti titi
Lodo re ko tu ja lu gutter , ke tu jo ma fi se yeye nbe
Be ba ti e gbe nko , se ogo olorun lo n fara han yen
Gbogbo awon oko oloko to ye ko dari sile lati ibise beer parlor eh ni won tii na
Gbogbo owo osu won , e tun fi nkan si pepper soup won
Ehhhhh , e tun ma gbedi , tun ma fi idi juru si won nitori owo te gba lowo wan
Toba di ojo sunday e tun lo ile ijosin
Eyin sat un kan mo gi sin ni
Pelu ise ati iwa owo re
Ronu piwada ko ese sile
Kaa rin o sinu ife baba
Ehhh, oni lati yipada , ko si ko orin yin pelu mi
Apata aiyeraye se ibi isadi mi , je ki omi oun eje
Tan san lati iya re, tan sa lati iya re
Se iwosan fese mi
Yoo se iwosan fun ese re bi o pa pi nu lati yipada
Ehn, iwo iyawo ile mo de odo e
Iwo to je wiepe toti ka maa ba jiya la se ya maa jiya lofa
Loko re ni joko nle maa toju awon omo , maa toju ille
Je ke mi ma lo sise , kin ma mowo wale
Sugon a ba o nibi a fi osi , yara onikinni yara onilekji lo maa wo kakakiri pelu iro laya
Oni we fun awon omo , toba ti fun won lounje tan eyin omo e maa lo sere lekunle
Loba bere sin i soso kuso kakakiri adugbo
Haaaa, bami lo korin kan oni
Erun mii a koba mii, erun mii a koba mi
Ejo e lejo la ro
Ki o ni ki a mu mi wa
Lugbe oro baa gbeyin yo
Ki o ni kin a to terun mii, enu mi yaa koba mii
Se enu re o wani koba e bayii
Nigba tii ara ile keji ti ara ile keta ba gbo
To ba penu won po won daru eke le o lori
Eehhhhhh, erun mii a koba mii, erun mii a koba mi
Ejo e lejo la ro
Ki o ni ki a mu mi wa
Lugbe oro baa gbeyin yo
Ki o ni kin a to terun mii, enu mi raa koba mii
Enu re o gbodo koba e oo iyawo ile
Ehh bo lo se wa se bayi
To je pe to oko re ban lo bise laaro gbogbo eyan lon mo
O lock aso re lorun ni , toni ti o ba fi owo toto o le ko gbodo lo
Toba dosan o fa abo lori awon ara ile yin , tii landlord ba de losan yo maa pari ija
Ija ni o pari tititi oko e yo fi de lale tii gbogbo eyan yo tun fi mop e oke re tii de
Awon ara ile yin gan ti da e mo ladugbo o ma gbo ara le e tun ti bere pelu oko e
Awon iyawo mi ewe o , awon mi e ja , won e ta nitiwon
Sugbon lataro titi to fi da le , won le ro ro maya, wa n we ,wan se ounje , won maa da ka je kakiri adugbo ni
Omo won bayi bi o se fakun le mu , o le yi ti n ba lo school , yi o wo aso gigan lo ni
Aso school e yo tii gan
Haa e tii ri iya e r’omo … se iru iyawo be ni maa n wu oko
Toba ya e le oko yin sita, ara ese yin lowa o pe n le oko yin sita
Eyin gan le n kowon si yoyo
Eyin oko na e gbo , awon nkan te le se fi aya yin le le ma se fun girlfriend
Gbogbo owo te le na fun iyawo ile , e ma na fun girlfriend … awon ofe kan tun wa te maa n
Da lara pelu awon girlfriend yii , e le da iru e lara fun iseju marun ni le , e tii ma gbo
E wan i gbogbo yen nisin , e ni ba iyawo yin jade
E maa gbo ni sho niwaju to ba debe loun
Ehn so fun won pee mi na fe de , ewa ma nowo yalayolo ni ta
Ita lomo yin tin da , e da ninu le , elomi a si ma wole lago kekekeninu awon okunrin
Bi ago 1 ago 2, haa nibo la fe ba iyara ja bayi
Nje senu waa o ni koba wa abi iwa wa…
Iwa gan o koba wa
Eje a lo jawo …. Onidajo aye maa n bo
Ijoba orun ku dede araye e yii pade
Onidajo aye n bo ti o bere lowo e
Onidajo aye n bo ti o bere lowo mi
Bawo lo se lo, igbesi aye wa
Tori naa ronu re wo … arakunrin ro nu re wo
Arabirin ro nu re wo, kesu ma fi o se yeye
Ronu re wo arakunrin ronu e wo arabirinronu re wo
Kesu ma fi e sere je
Hmmmmm awa iranse olorun eyin iranse olorun ti ajogun ijoba re
Oro kan wa o nitori wipe awa gangan ni agba te lori pantete bayi
Bi eyan ba de yo itigi to n be loju omo lakeji e ti o ba yo ti e
A je pe kape iru oni tohun yen lolo ju kan, oloju kan ni wa o
Bi a ba yo itigi loju awon eniyan ti a ba yo itigi oju ara wa
Wo ise olorun to n se sho n te n di, boya olorin emi ni o
Se nigba to n ko orin emi yen so ko lokan ko , o duro loro kristi apata ile miran iyanrin ni
Baa tin ko
Sho te n di se o wa okiki kakiri, se ko se pe awon eyan to so fun pe ko ma wa ijoba olorun se ko se pe eyi to ku leyin re niwo fun rara ewa
To fi ijoba olorun sile …
Awon iranse olorun mi to pe ara won lolorin won a si ma korin wa ma bura won , won a ma tako oro so
Tele yi ba korin to bu towun , towun na a tun gbe ti e naa a tun bu ti e
A lawa ma yato si won , olorin aye la gbo ton ko iru e nigbakan
Igba wo lo tun wa da bayi lodo wa
Ronu re wo arakunrin ronu e wo arabirinronu re wo
Kesu ma fi o se yeye
Se esu o wa fi e se yeye bayi abi o fure pe esu fi e se yeye
Nigba ta ba pe o sile ijosin tori pe a mo wipe akorin emi ni e
Pe orun awon eniyan yi o si lati gba ire to wa debe to ko orin to mu ogo
Jade wa , o ko orin to ni igbala ninu , o ko orin tawon eyan yi o fi aye won fun jesu
O sip e ara enii akorin emi
Hmm se olorin emi ni e fun ra e abi won kon pe e be
Tori to ba fe lo ko orin emi ta n wi yin na , yo ti muti yo keri
Toba tun ko tan a tun gbe igba oti re .. Ehhh
Ronu re wo arakunrin ronu re wo arabirin ro nu re wo
Kesu ma fi e se ere je
Ohun ma dawole ti ma deni egan lo do re o
Ohun ma dawole ti ma deni iko sile oo
O ma jare o jesu ma ma je kin dawole
O maa jare o baba ma ma je kin kabuki lodo re
O ma jare o jesu maa ma je kin dawole
Haaaaaa
Ese loro o
Iku ni ereese
Orun apadi lese gbomo eniyan re
Tori na beleda re laja loni ooo
Ko ma ba kuno ile ologo
Orin iya mi olorin nuu, ese maa loro
Iku ni ere ese , orun apandii ohun ni gbeni re
Ba eleda ra laja loni , ko ma ba kuno ile ologo
Tori pe
Gbogbo mapa mapa pata ile aye lomo
Gbogbo mo moyanni ilu pata ile aye lomo
Oro mi ni e gbo e ma wo se mii ile aye lomo
Ma jaye oni mi o meyin ola ile aye lo mo
Ma koro si won lenu kilo fe se fun mi , ile aye lomo
A ma ku lojo kan , a ma kuu lojokan patapata
Eniyan a ku , ara aye a rorun … olorun nikan ni o ku
Eyan ku ,ko si ba se le mo se to
Ologbo aye kan o ta koko seti aso ri
Awon omoran kan won iye iyepe ile debi teti ka teti okun
Eh beniyan ba de ku tan , e mo bi awon eniyan won se n tara
Benikan ba ku ninu ebi , eri ba won ma se beri si ni t’ara
Ekan a de lati ilu oyinbo , awon kan a de lati ilu won
Awon kan a de lati abule , won ma wa pari , won a bo bata ofo si enu ono ile
Gbogbo wa a ni ri babt ofo senu ono ile wa o
Bi eyan ba ku ko sib o se le darugboto won bo bata senu ona ile won
O le ma je tofo , won bo bata senu ono
Won ma waa pariwo , omo o so ti e , iyawo o so ti e , eni to close mo baba tabi iya ju yo
Ma so ti e … ani
Iwo yii idunta a jo je
Iwo yi eshi a jo damoran … igba to dana lo wo dariwo a o rimo
Be lo se ma ri fun emi ati e
Ahan I spoke with dad yesterday , ohh whats this
Oyinbo a ma jabo lati enu awon omo ilu oyinbo
Haaa ..baba lagbaja o so fun mi pe bowun ma se ririn owun re , iyen niyen lenu iyawo
Bo de je oko ni a so ti e
Gbogbo eniyan to sese ba soro tan boya lori ero ibanisoro boya tii won sese wo tan lori television won ma so tiwon
Omo naa a kawo leri , awon eniyan to je wipe won feran oku ati won feran e gan
A maa janra mole wipe shey o to ni , o tii ku abi
Haaaa
Iwoyi idunta o a jo je
Iwoyi eshi a jo da moran
Igba to dana lo wa dariwo a o rimo
Be lo se ma ri fun emi ati e
Toba ti se gbogbo iyen tan kilo kuu ni lati gbe photo oku
Nigba to wa laye awa feyin ke sinu photo
Photo yin ni won yo gbe sori tabili , won gbe iwe siwaju e wan a fi biro si
Onikaluku a wa to , won a ma ko sibe
Boje ika na lo ni , boje eyan kan to lola tabi eyan ta o ti e mo
Sugbon oni kaluku yo ma wa ko ti e , waa mu biro
A fe o sugbon jesu fe o juu
Sun re
Telo miran ba de be, a ni olufe mi owon sun re
Orisirisi ni won maa n ko , to ba ti ri iwe pelu foto won a mo ko orisirissibe
Gege bi eyin na ti mo wipe o si kuu ijo wake keeping , won
Wa lo gbe oku wa lati mortuary , won ti mu ijo ke keeping ati ojo oku
Toba tii gboku de , won a ti mura fun
A wa ninu posi nbe, waa te si ile tori wakekeeping
Onikaliku a ma koja , won a ma wo oju oku fun iwo ikeyin, to baa tin wo oju re elo mi a ma ni ha afi gba ti okumrim yin lo ti o sanwo yi na
Elo mi a si woju e a ni ehh baba dada
Elomi a tun wo a tun ni sotan baa rin bi e ni je a rin ba so bii e ni ja e so
Oy a e dide e wa se bo se maa n se
Nitori wipe laarin ota , ejo ikoko awon paramole ninu aye ta way i
Bi o ti ri awon to feran re , beni o ma ri awon ti o feran e
Nigba ti o wa laye awon kan feyin si o sugbon won feran e , inu won o da si o
O ma gbo beyan ba teti si okan wo , o ma gbo nkan ti onikaluku won so
Awwa kuro nibe , won gbe oku won fe lo se eto isinku niyen
Wa ma gbo ati gbe baba re le
A ti gbe baba re le
Ati gbe eeee ati gbe eee
Baba re le
A o gbe won, ati fi lele fun enyan lati ku len kan
Bibeli ni leyin re idajo ni
Odi dandan ka gbe won o , a o gbe won lo si ite ku
Nibi a tii se eto isinku legbe iboji fun won
Lobatan…. Ile aye ese mefa
Alagbere o ma tan sibe re
Gbogbo won dami mo ladugbo yi pee mi ni iyabe
Lobatan ooooo , gbogbo ise aje ati ise emere , ise osho, ibe lo pari si
Gbogbo ka muu ogo ologo ka de moa be , ka ko won sinu ahamo ka
De joko te won ri , ka me je ki won lo siwaju nitori
Awon ogun nlanla buruku buruku ta tii gboju le
Ehhh lo ba pari , awa gbe won lo si ite nbe
Won o se eto isinku bo se ye ko se
Won wa muu shovel fun awon ti erupe ba to sii
Won ni ko bu eru fun eru , erupe fun erupe
Bayi ni awon egbe akorin yo gbe iwe orin won soke , awon orin asayan fun oku
Eleyi to la mi la kaa to ye ki onigbagbo maa ronu nigba ti won ba ko lowo
Awon ni o wa ninu iwe orin yii
E gbo bi won ti n ko ikan lara won nii
A o pade leti odo
Odo didan odo didan ooo na
Pe lawon mimo leba odo to n san le ba ite na
O gbo ibeere e nii, A o pade leti odo , tese angeli tite
To mo gara bi cystalis

Follow Us On Facebook InstagramTwitter

Similar Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *